OLUWA, mo gbo pe Iwo

by YBH 420

1. OLUWA, mo gbo pe Iwo Nro ojo ‘bukun kiri; Itunu fun okan are, Ro ojo re s’ ori mi. An’ emi! Ro ojo re s’ ori mi! 2. Ma koja Baba Olore, Bi ese mi tile po; ‘Wo le fi mi sile, sugbon Jek’ anu Re ba le mi. An’ emi, Ro ojo re s’ ori mi! 3. Ma koja mi, Olugbala Jek’ emi le ro mo O; Emi nwa oju rere Re, Pe mi mo awon t’ O npe. An’ emi, Ro ojo re s’ ori mi! 4. Ma koja mi, Emi Mimo, ‘Wo le la ‘ju afoju; Eleri itoye Jesu, Soro ase na si mi. An’ emi, Ro ojo re s’ ori mi! 5. Mo ti sun fonfon nin’ ese, Mo bi O binu koja; Aiye ti de okan mi, jo Tu mi, k’ o dariji mi. An’ emi, Ro ojo re s’ ori mi! 6. Ife Olorun ti ki ye; Eje Krist’ iyebiye; Ore-ofe alainiwon; Gbe gbogbo re ga n’nu mi. An’ emi, Ro ojo re s’ ori mi! 7. Ma koja mi, dariji mi, Fa mi mora, Oluwa; ‘Gba O nf’ ibukun f’ elomi, Ma sai f’ ibukun fun mi. An’ emi, Ro ojo re s’ ori mi!